A kò ha ké onjẹ kuro niwaju oju wa, ayọ̀ ati inu didùn kuro ninu ile Ọlọrun wa? Irugbìn bajẹ ninu ebè wọn, a sọ aká di ahoro, a wó abà palẹ; nitoriti a mu ọ̀ka rọ. Awọn ẹranko ti nkerora to! awọn agbo-ẹran dãmu, nitoriti nwọn kò ni papa oko; nitõtọ, a sọ awọn agbo agùtan di ahoro. Oluwa, si ọ li emi o ké, nitori iná ti run pápa oko tutú aginju, ọwọ́ iná si ti jo gbogbo igi igbẹ. Awọn ẹranko igbẹ gbé oju soke si ọ pẹlu: nitoriti awọn iṣàn omi gbẹ, iná si ti jó awọn pápa oko aginju run.
Kà Joel 1
Feti si Joel 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joel 1:16-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò