Job 9:30-33

Job 9:30-33 YBCV

Bi mo tilẹ fi omi òjo didì wẹ̀ ara mi, ti mo fi omi-aró wẹ̀ ọwọ mi mọ́, Sibẹ iwọ o gbe mi bọ̀ inu ihò ọ̀gọdọ, aṣọ ara mi yio sọ mi di ẹni-irira. Nitori on kì iṣe enia bi emi, ti emi o fi da a lohùn ti awa o fi pade ni idajọ. Bẹ̃ni kò si alatunṣe kan lagbedemeji wa, ti iba fi ọwọ rẹ̀ le awa mejeji lara.