Job 39:26-30

Job 39:26-30 YBCV

Awodi a ma ti ipa ọgbọ́n rẹ fò soke, ti o si nà iyẹ apa rẹ̀ siha gusu? Idì a ma fi aṣẹ rẹ fò lọ soke, ki o si lọ itẹ ìtẹ rẹ̀ si oke giga? O ngbe o si wọ̀ li ori apata, lori palapala okuta ati ibi ori oke. Lati ibẹ lọ ni ima wá ọdẹ kiri, oju rẹ̀ si riran li òkere rere. Awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu a ma mu ẹ̀jẹ, nibiti okú ba gbe wà, nibẹ li on wà pẹlu.