Job 38:12-18

Job 38:12-18 YBCV

Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀? Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀. Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa. A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́. Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla? A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú? Iwọ̀ moye ibú aiye bi? sọ bi iwọ ba mọ̀ gbogbo rẹ̀?