Job 28:20-24

Job 28:20-24 YBCV

Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun.