Job 14:16-17

Job 14:16-17 YBCV

Ṣugbọn nisisiyi iwọ nkaye iṣisẹ mi, iwọ kò fà ọwọ rẹ kuro nitori ẹ̀ṣẹ mi. A fi edidi di irekọja mi sinu àpo, iwọ si rán aiṣedede mi pọ̀.