Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ. Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira. Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira? Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ. Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai. Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ. Mo mọ̀ pe irú-ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe; ṣugbọn ẹ nwá ọ̀na ati pa mi, nitori ọ̀rọ mi kò ri àye ninu nyin. Ohun ti emi ti ri lọdọ Baba ni mo nsọ: ẹnyin pẹlu si nṣe eyi ti ẹnyin ti gbọ lati ọdọ baba nyin. Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Abrahamu ni baba wa. Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe, ẹnyin iba ṣe iṣẹ Abrahamu. Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nwá ọ̀na ati pa mi, ẹniti o sọ otitọ fun nyin, eyi ti mo ti gbọ́ lọdọ Ọlọrun: Abrahamu kò ṣe eyi. Ẹnyin nṣe iṣẹ baba nyin. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, A ko bí wa nipa panṣaga: a ni Baba kan, eyini li Ọlọrun.
Kà Joh 8
Feti si Joh 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 8:31-41
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò