Joh 5:25-29

Joh 5:25-29 YBCV

Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Wakati na mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn okú yio gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun: awọn ti o ba gbọ yio si yè. Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀; O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia. Ki eyi ki o máṣe yà nyin li ẹnu; nitoripe wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn rẹ̀. Nwọn o si jade wá; awọn ti o ṣe rere, si ajinde ìye; awọn ti o si ṣe buburu, si ajinde idajọ.

Àwọn fídíò fún Joh 5:25-29