Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun.
Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀.
Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi?
Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀.
Ẹnyin kò ha nwipe, O kù oṣù mẹrin, ikorè yio si de? wo o, mo wi fun nyin, Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wó oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na.
Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀.
Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ.
Mo rán nyin lọ ikore ohun ti ẹ kò ṣiṣẹ le lori: awọn ẹlomiran ti ṣiṣẹ, ẹnyin si wọ̀ inu iṣẹ wọn lọ.
Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu na wá si gbà a gbọ́, nitori ọ̀rọ obinrin na, o jẹri pe, O sọ gbogbo ohun ti mo ti ṣe fun mi.
Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji.
Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀;
Nwọn si wi fun obinrin na pe, Ki iṣe nitori ọrọ rẹ mọ li awa ṣe gbagbọ: nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye.
Lẹhin ijọ meji o si ti ibẹ̀ kuro, o lọ si Galili.
Nitori Jesu tikararẹ̀ ti jẹri wipe, Woli ki ini ọlá ni ilẹ on tikararẹ̀.
Nitorina nigbati o de Galili, awọn ara Galili gbà a, nitoriti nwọn ti ri ohun gbogbo ti o ṣe ni Jerusalemu nigba ajọ; nitori awọn tikarawọn lọ si ajọ pẹlu.
Bẹ̃ni Jesu tún wà si Kana ti Galili, nibiti o gbé sọ omi di waini. Ọkunrin ọlọla kan si wà, ẹniti ara ọmọ rẹ̀ kò da ni Kapernaumu.
Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Judea wá si Galili, o tọ̀ ọ wá, o si mbẹ̀ ẹ, ki o le sọkalẹ wá ki o mu ọmọ on larada: nitoriti o wà li oju ikú.
Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Bikoṣepe ẹnyin ba ri àmi ati iṣẹ iyanu, ẹnyin kì yio gbagbọ́ lai.
Ọkunrin ọlọla na wi fun u pe, Oluwa, sọkalẹ wá, ki ọmọ mi ki o to ku.
Jesu wi fun u pe, Mã ba ọ̀na rẹ lọ; ọmọ rẹ yè. Ọkunrin na si gbà ọ̀rọ ti Jesu sọ fun u gbọ́, o si lọ.
Bi o si ti nsọkalẹ lọ, awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pade rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, ọmọ rẹ yè.
Nigbana li o bère wakati ti o bẹ̀rẹ si isàn lọwọ wọn. Nwọn si wi fun u pe, Li ana, ni wakati keje, ni ibà na fi i silẹ.
Bẹ̃ni baba na mọ̀ pe, ni wakati kanna ni, ninu eyi ti Jesu wi fun u pe, Ọmọ rẹ yè: on tikararẹ̀ si gbagbọ́, ati gbogbo ile rẹ̀.
Eyi ni iṣẹ́ ami keji, ti Jesu ṣe nigbati o ti Judea jade wá si Galili.