Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ? Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe, Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na? Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá. Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi? Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀. Ẹnyin kò ha nwipe, O kù oṣù mẹrin, ikorè yio si de? wo o, mo wi fun nyin, Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wó oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na. Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀.
Kà Joh 4
Feti si Joh 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 4:27-36
7 Days
New Year. A New Day. God created these transitions to remind us that He is the God of New Beginnings. If God can speak the world into existence, He can certainly speak into the darkness of your life, creating for you a new beginning. Don’t you just love fresh starts! Just like this reading plan. Enjoy!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò