Joh 2:1-25

Joh 2:1-25 YBCV

NI ijọ kẹta a si nṣe igbeyawo kan ni Kana ti Galili; iya Jesu si mbẹ nibẹ̀: A si pè Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu, si ibi igbeyawo. Nigbati waini si tan, iya Jesu wi fun u pe, Nwọn kò ni waini. Jesu wi fun u pe, Kini ṣe temi tirẹ, obinrin yi? wakati mi kò iti de. Iya rẹ̀ wi fun awọn iranṣẹ pe, Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e. Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti. O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ. Bi olori àse si ti tọ́ omi ti a sọ di waini wò, ti ko si mọ̀ ibi ti o ti wá (ṣugbọn awọn iranṣẹ ti o bù omi na wá mọ̀), olori àse pè ọkọ iyawo, O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi. Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́. Lẹhin eyi, o sọkalẹ lọ si Kapernamu, on ati iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nwọn kò si gbé ibẹ̀ li ọjọ pupọ. Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalemu, O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko: O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu. O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ranti pe, a ti kọ ọ pe, Itara ile rẹ jẹ mi run. Nigbana li awọn Ju dahùn, nwọn si wi fun u pe Àmi wo ni iwọ fi hàn wa, ti iwọ fi nṣe nkan wọnyi? Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ wó tẹmpili yi palẹ̀, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró. Nigbana li awọn Ju wipe, Ọdún mẹrindiladọta li a fi kọ́ tẹmpili yi, iwọ o ha si gbé e ró ni ijọ mẹta? Ṣugbọn on nsọ ti tẹmpili ara rẹ̀. Nitorina nigbati o jinde kuro ninu okú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ranti pe, o ti sọ eyi fun wọn; nwọn si gbà iwe-mimọ́ gbọ́, ati ọ̀rọ ti Jesu ti sọ. Nigbati o si wà ni Jerusalemu, ni ajọ irekọja, lakoko ajọ na, ọ̀pọ enia gbà orukọ rẹ̀ gbọ nigbati nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀ ti o ṣe. Ṣugbọn Jesu kò gbé ara le wọn, nitoriti o mọ̀ gbogbo enia. On ko si wa ki ẹnikẹni ki o jẹri enia fun on: nitoriti on mọ̀ ohun ti mbẹ ninu enia.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ