Joh 19:39-42

Joh 19:39-42 YBCV

Nikodemu pẹlu si wá, ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru lakọṣe, o si mu àdapọ̀ ojia ati aloe wá, o to ìwọn ọgọrun litra. Bẹni nwọn gbé okú Jesu, nwọn si fi aṣọ ọ̀gbọ dì i pẹlu turari, gẹgẹ bi iṣe awọn Ju ti ri ni isinkú wọn. Agbala kan si wà nibiti a gbé kàn a mọ agbelebu; ibojì titun kan sí wà ninu agbala na, ninu eyiti a ko ti itẹ́ ẹnikẹni si ri. Njẹ nibẹ ni nwọn si tẹ́ Jesu si, nitori Ipalẹmọ́ awọn Ju; nitori ibojì na wà nitosi.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ