Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi. A gbé ohun èlo kan kalẹ nibẹ̀ ti o kún fun ọti kikan: nwọn si fi sponge ti o kun fun ọti kikan, sori igi hissopu, nwọn si fi si i li ẹnu. Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Nitori o jẹ ọjọ Ipalẹmọ, ki okú wọn ma bà wà lori agbelebu li ọjọ isimi, (nitori ojọ nla ni ọjọ isimi na) nitorina awọn Ju bẹ̀ Pilatu pe ki a ṣẹ egungun itan wọn, ki a si gbe wọn kuro. Nitorina awọn ọmọ-ogun wá, nwọn si ṣẹ́ egungun itan ti ekini, ati ti ekeji, ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn nigbati nwọn de ọdọ Jesu, ti nwọn si ri pe, o ti kú na, nwọn kò si ṣẹ́ egungun itan rẹ̀: Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ-ogun na fi ọ̀kọ gún u li ẹgbẹ, lojukanna ẹ̀jẹ ati omi si tú jade. Ẹniti o ri i si jẹri, otitọ si li ẹrí rẹ̀: o si mọ̀ pe õtọ li on wi, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́.
Kà Joh 19
Feti si Joh 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 19:28-35
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò