Joh 19:26-27

Joh 19:26-27 YBCV

Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ! Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ