Joh 19:25-30

Joh 19:25-30 YBCV

Iya Jesu ati arabinrin iya rẹ̀ Maria aya Klopa, ati Maria Magdalene, si duro nibi agbelebu. Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ! Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀. Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi. A gbé ohun èlo kan kalẹ nibẹ̀ ti o kún fun ọti kikan: nwọn si fi sponge ti o kun fun ọti kikan, sori igi hissopu, nwọn si fi si i li ẹnu. Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ