Joh 18:33-38

Joh 18:33-38 YBCV

Nitorina Pilatu tún wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si pè Jesu, o si wi fun u pe, Ọba awọn Ju ni iwọ iṣe? Jesu dahùn pe, Iwọ sọ eyi fun ara rẹ ni, tabi awọn ẹlomiran sọ ọ fun ọ nitori mi? Pilatu dahùn wipe, Emi iṣe Ju bi? Awọn orilẹ-ède rẹ, ati awọn olori alufa li o fà ọ le emi lọwọ: kini iwọ ṣe? Jesu dahùn wipe, Ijọba mi kì iṣe ti aiye yi: ibaṣepe ijọba mi iṣe ti aiye yi, awọn onṣẹ mi iba jà, ki a má bà fi mi le awọn Ju lọwọ: ṣugbọn nisisiyi ijọba mi kì iṣe lati ihin lọ. Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi. Pilatu wi fun u pe, Kili otitọ? Nigbati o si ti wi eyi tan, o tún jade tọ̀ awọn Ju lọ, o si wi fun wọn pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.

Àwọn fídíò fún Joh 18:33-38