Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà. Nitorina bi Jesu ti mọ̀ ohun gbogbo ti mbọ̀ wá ba on, o jade lọ, o si wi fun wọn pe, Tali ẹ nwá? Nwọn si da a lohùn wipe, Jesu ti Nasareti. Jesu si wi fun wọn pe, Emi niyi. Ati Judasi pẹlu, ẹniti o fi i hàn, duro pẹlu wọn. Nitorina bi o ti wi fun wọn pe, Emi niyi, nwọn bi sẹhin, nwọn si ṣubu lulẹ.
Kà Joh 18
Feti si Joh 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 18:3-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò