Nigbana li olori alufa bi Jesu lẽre niti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati niti ẹkọ́ rẹ̀. Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ. Ẽṣe ti iwọ fi mbi mi lẽre? bere lọwọ awọn ti o ti gbọ́ ọ̀rọ mi, ohun ti mo wi fun wọn: wo o, awọn wọnyi mọ̀ ohun ti emi wi. Bi o si ti wi eyi tan, ọkan ninu awọn onṣẹ ti o duro tì i fi ọwọ́ rẹ̀ lù Jesu, wipe, Olori alufa ni iwọ nda lohùn bẹ̃? Jesu da a lohùn wipe, Bi mo ba sọrọ buburu, jẹri si buburu na: ṣugbọn bi rere ba ni, ẽṣe ti iwọ fi nlù mi?
Kà Joh 18
Feti si Joh 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 18:19-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò