Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn; Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi. Ogo ti iwọ ti fifun mi li emi si ti fifun wọn; ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ ọ̀kan; Emi ninu wọn, ati iwọ ninu mi, ki a le ṣe wọn pé li ọ̀kan; ki aiye ki o le mọ̀ pe, iwọ li o rán mi, ati pe iwọ si fẹràn wọn gẹgẹ bi iwọ ti fẹràn mi.
Kà Joh 17
Feti si Joh 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 17:20-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò