Joh 16:7-11

Joh 16:7-11 YBCV

Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin. Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ: Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́; Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́; Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ