Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na? Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi. Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i. Filippi wi fun u pe, Oluwa, fi Baba na hàn wa, o si to fun wa. Jesu wi fun u pe, Bi akokò ti mo ba nyin gbé ti pẹ to yi, iwọ kò si ti imọ̀ mi sibẹ̀ Filippi? Ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wipe, Fi Baba hàn wa? Iwọ kò ha gbagbọ́ pe, Emi wà ninu Baba, ati pe Baba wà ninu mi? ọ̀rọ ti emi nsọ fun nyin, emi kò da a sọ; ṣugbọn Baba ti ngbé inu mi, on ni nṣe iṣẹ rẹ̀. Ẹ gbà mi gbọ́ pe, emi wà ninu Baba, Baba si wà ninu mi: bikoṣe bẹ̃, ẹ gbà mi gbọ́ nitori awọn iṣẹ na pãpã. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.
Kà Joh 14
Feti si Joh 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 14:5-12
5 Days
Who are you becoming? If you envision yourself at age 70, 80, or 100, what kind of person do you see on the horizon? Does the projection in your mind fill you with hope? Or dread? In this devotional, John Mark Comer shows us how we can be spiritually formed to become more like Jesus day by day.
5 Awọn ọjọ
Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!
7 Days
Is it really possible to experience peace when life is painful? The short answer: yes, but not in our own power. In a year that has left us feeling overwhelmed, many of us are left with questions. In this 7-day Bible Plan, accompanying Pastor Craig Groeschel’s message series, we’ll discover how to find the Missing Peace we all crave.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò