Joh 13:31-35

Joh 13:31-35 YBCV

Nitorina nigbati o jade lọ tan, Jesu wipe, Nisisiyi li a yìn Ọmọ-enia logo, a si yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀. Bi a ba yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀, Ọlọrun yio si yìn i logo ninu on tikararẹ̀, yio si yìn i logo nisisiyi. Ẹnyin ọmọde, nigba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin. Ẹnyin ó wá mi: ati gẹgẹ bi mo ti wi fun awọn Ju pe, Nibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì o le wá; bẹ̃ni mo si wi fun nyin nisisiyi. Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin. Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin.

Àwọn fídíò fún Joh 13:31-35