Joh 13:21-27

Joh 13:21-27 YBCV

Nigbati Jesu ti wi nkan wọnyi tan, ọkàn rẹ̀ daru ninu rẹ̀, o si jẹri, o si wipe, Lõtọ lõtọ ni mo wi fun nyin pe, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nwò ara wọn loju, nwọn nṣiye-meji ti ẹniti o wi. Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn. Nitorina ni Simoni Peteru ṣapẹrẹ si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti ẹniti o nsọ. Ẹniti o nrọ̀gún li àiya Jesu wi fun u pe, Oluwa, tani iṣe? Nitorina Jesu dahùn pe, On na ni, ẹniti mo ba fi òkele fun nigbati mo ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o fifun Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan.

Àwọn fídíò fún Joh 13:21-27