Joh 12:12-33

Joh 12:12-33 YBCV

Ni ijọ keji nigbati ọ̀pọ enia ti o wá si ajọ gbọ́ pe, Jesu mbọ̀ wá si Jerusalemu, Nwọn mu imọ̀-ọ̀pẹ, nwọn si jade lọ ipade rẹ̀, nwọn si nkigbe pe, Hosanna: Olubukun li ẹniti mbọ̀wá li orukọ Oluwa, Ọba Israeli. Nigbati Jesu si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan, o gùn u; gẹgẹ bi a ti kọwe pe, Má bẹ̀ru, ọmọbinrin Sioni: wo o, Ọba rẹ mbọ̀ wá, o joko lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Nkan wọnyi kò tète yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ṣugbọn nigbati a ṣe Jesu logo, nigbana ni nwọn ranti pe, a kọwe nkan wọnyi niti rẹ̀, ati pe, on ni nwọn ṣe nkan wọnyi si. Nitorina ijọ enia ti o wà lọdọ rẹ̀, nigbati o pè Lasaru jade ninu iboji rẹ̀, ti o si jí i dide kuro ninu okú, nwọn jẹri. Nitori eyi ni ijọ enia si ṣe lọ ipade rẹ̀, nitoriti nwọn gbọ́ pe o ti ṣe iṣẹ àmi yi. Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ. Awọn Hellene kan si wà ninu awọn ti o gòke wá lati sìn nigba ajọ: Awọn wọnyi li o tọ̀ Filippi wá, ẹniti iṣe ará Betsaida ti Galili, nwọn si mbère lọwọ rẹ̀, wipe, Alàgba, awa nfẹ ri Jesu. Filippi wá, o si sọ fun Anderu; Anderu ati Filippi wá, nwọn si sọ fun Jesu. Jesu si da wọn lohùn wipe, Wakati na de, ti a o ṣe Ọmọ-enia logo. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe wóro alikama ba bọ́ si ilẹ̀, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọ̀pọlọpọ eso. Ẹniti o ba fẹ ẹmí rẹ̀ yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si korira ẹmi rẹ̀ li aiye yi ni yio si pa a mọ́ titi fi di ìye ainipẹkun. Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, ki o ma tọ̀ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibẹ̀ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun. Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi. Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo. Nitorina ijọ enia ti o duro nibẹ̀, ti nwọn si gbọ́ ọ, wipe, Ãrá nsán: awọn ẹlomiran wipe, Angẹli kan li o mba a sọrọ. Jesu si dahùn wipe, Ki iṣe nitori mi li ohùn yi ṣe wá, bikoṣe nitori nyin. Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade. Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi. Ṣugbọn o wi eyi, o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.

Àwọn fídíò fún Joh 12:12-33

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Joh 12:12-33

Joh 12:12-33 - Ni ijọ keji nigbati ọ̀pọ enia ti o wá si ajọ gbọ́ pe, Jesu mbọ̀ wá si Jerusalemu,
Nwọn mu imọ̀-ọ̀pẹ, nwọn si jade lọ ipade rẹ̀, nwọn si nkigbe pe, Hosanna: Olubukun li ẹniti mbọ̀wá li orukọ Oluwa, Ọba Israeli.
Nigbati Jesu si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan, o gùn u; gẹgẹ bi a ti kọwe pe,
Má bẹ̀ru, ọmọbinrin Sioni: wo o, Ọba rẹ mbọ̀ wá, o joko lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
Nkan wọnyi kò tète yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ṣugbọn nigbati a ṣe Jesu logo, nigbana ni nwọn ranti pe, a kọwe nkan wọnyi niti rẹ̀, ati pe, on ni nwọn ṣe nkan wọnyi si.
Nitorina ijọ enia ti o wà lọdọ rẹ̀, nigbati o pè Lasaru jade ninu iboji rẹ̀, ti o si jí i dide kuro ninu okú, nwọn jẹri.
Nitori eyi ni ijọ enia si ṣe lọ ipade rẹ̀, nitoriti nwọn gbọ́ pe o ti ṣe iṣẹ àmi yi.
Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ.

Awọn Hellene kan si wà ninu awọn ti o gòke wá lati sìn nigba ajọ:
Awọn wọnyi li o tọ̀ Filippi wá, ẹniti iṣe ará Betsaida ti Galili, nwọn si mbère lọwọ rẹ̀, wipe, Alàgba, awa nfẹ ri Jesu.
Filippi wá, o si sọ fun Anderu; Anderu ati Filippi wá, nwọn si sọ fun Jesu.
Jesu si da wọn lohùn wipe, Wakati na de, ti a o ṣe Ọmọ-enia logo.
Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe wóro alikama ba bọ́ si ilẹ̀, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọ̀pọlọpọ eso.
Ẹniti o ba fẹ ẹmí rẹ̀ yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si korira ẹmi rẹ̀ li aiye yi ni yio si pa a mọ́ titi fi di ìye ainipẹkun.
Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, ki o ma tọ̀ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibẹ̀ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun.

Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi.
Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo.
Nitorina ijọ enia ti o duro nibẹ̀, ti nwọn si gbọ́ ọ, wipe, Ãrá nsán: awọn ẹlomiran wipe, Angẹli kan li o mba a sọrọ.
Jesu si dahùn wipe, Ki iṣe nitori mi li ohùn yi ṣe wá, bikoṣe nitori nyin.
Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade.
Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi.
Ṣugbọn o wi eyi, o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.Joh 12:12-33 - Ni ijọ keji nigbati ọ̀pọ enia ti o wá si ajọ gbọ́ pe, Jesu mbọ̀ wá si Jerusalemu,

Ṣugbọn o wi eyi, o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.