Joh 11:28-36

Joh 11:28-36 YBCV

Nigbati o si ti wi eyi tan, o lọ, o si pè Maria arabinrin rẹ̀ sẹhin wipe, Olukọni de, o si npè ọ. Nigbati o gbọ́, o dide lọgan, o si wá sọdọ rẹ̀. Jesu kò sá ti iwọ̀ ilu, ṣugbọn o wà nibikanna ti Marta pade rẹ̀. Nitorina awọn Ju ti o wà lọdọ rẹ̀ ninu ile, ti nwọn ntù u ninu, nigbati nwọn ri ti Maria dide kánkan, ti o si jade, nwọn tẹ̀le e, nwọn ṣebi o nlọ si ibojì lọ isọkun nibẹ̀. Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú. Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ, O si wipe, Nibo li ẹnyin gbé tẹ́ ẹ si? Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, wá wò o. Jesu sọkun. Nitorina awọn Ju wipe, sa wo o bi o ti fẹràn rẹ̀ to!

Àwọn fídíò fún Joh 11:28-36