Marta wi fun u pe, Mo mọ̀ pe yio jinde li ajinde nigbẹhin ọjọ. Jesu wi fun u pe, Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ́, bi o tilẹ kú, yio yè: Ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gbà mi gbọ́, kì yio kú lailai. Iwọ gbà eyi gbọ́? O wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa: emi gbagbọ́ pe, iwọ ni Kristi na Ọmọ Ọlọrun, ẹniti mbọ̀ wá aiye.
Kà Joh 11
Feti si Joh 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 11:24-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò