Awọn Ju si tún he okuta, lati sọ lù u. Jesu da wọn lohùn pe, Ọpọlọpọ iṣẹ rere ni mo fi hàn nyin lati ọdọ Baba mi wá; nitori ewo ninu iṣẹ wọnni li ẹnyin ṣe sọ mi li okuta? Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ́ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun. Jesu da wọn lohùn pe, A kò ha ti kọ ọ ninu ofin nyin pe, Mo ti wipe, ọlọrun li ẹnyin iṣe? Bi o ba pè wọn li ọlọrun, awọn ẹniti a fi ọ̀rọ Ọlọrun fun, a kò si le ba iwe-mimọ́ jẹ, Ẹnyin ha nwi niti ẹniti Baba yà si mimọ́, ti o si rán si aiye pe, Iwọ nsọrọ-odi, nitoriti mo wipe Ọmọ Ọlọrun ni mi?
Kà Joh 10
Feti si Joh 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 10:31-36
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò