Jer 7:30-31

Jer 7:30-31 YBCV

Nitori awọn ọmọ Juda ti ṣe buburu niwaju mi, li Oluwa wi; nwọn ti gbe ohun irira wọn kalẹ sinu ile ti a pe li orukọ mi, lati ba a jẹ. Nwọn si ti kọ́ ibi giga Tofeti, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati sun awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin wọn ninu iná; aṣẹ eyiti emi kò pa fun wọn, bẹ̃ni kò si wá si inu mi.