Jer 7:13-15

Jer 7:13-15 YBCV

Njẹ nisisiyi, nitori ẹnyin ti ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi, li Oluwa wi, ti emi si ba nyin sọ̀rọ, ti emi ndide ni kutukutu ti mo si nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́; ti emi si npè nyin, ṣugbọn ẹnyin kò dahùn. Nitorina li emi o ṣe si ile yi, ti a pè ni orukọ mi, ti ẹ gbẹkẹle, ati si ibi ti emi fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin, gẹgẹ bi emi ti ṣe si Ṣilo. Emi o si ṣá nyin tì kuro niwaju mi, gẹgẹ bi mo ti ṣá awọn arakunrin nyin tì, ani gbogbo iru-ọmọ Efraimu.