Nitorina bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, nitori ẹnyin sọ ọ̀rọ yi, sa wò o, emi o sọ ọ̀rọ mi li ẹnu rẹ di iná, ati awọn enia yi di igi, yio si jo wọn run.
Wò o emi o mu orilẹ-ède kan wá sori nyin lati ọ̀na jijin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa wi, orilẹ-ède alagbara ni, orilẹ-ède lati igbãni wá ni, orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀ ede rẹ̀, bẹ̃ni iwọ kò gbọ́ eyiti o nwi.
Apó ọfa rẹ̀ dabi isa-okú ti a ṣi, akọni enia ni gbogbo wọn.
On o si jẹ ikore rẹ ati onjẹ rẹ, nwọn o jẹ awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin rẹ, nwọn o si jẹ agbo rẹ ati ọwọ́-ẹran rẹ, nwọn o jẹ àjara rẹ ati igi ọ̀pọtọ rẹ, nwọn o fi idà sọ ilu olodi rẹ ti iwọ gbẹkẹle di ahoro.
Ṣugbọn li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi, emi kì yio ṣe iparun nyin patapata.
Yio si ṣe, nigbati ẹnyin o wipe: Ẽṣe ti Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo ohun wọnyi si wa? nigbana ni iwọ o da wọn lohùn: Gẹgẹ bi ẹnyin ti kọ̀ mi, ti ẹnyin si nsìn ọlọrun ajeji ni ilẹ nyin, bẹ̃ni ẹnyin o sin alejo ni ilẹ ti kì iṣe ti nyin.
Kede eyi ni ile Jakobu, pokiki rẹ̀ ni Juda wipe,
Ẹ gbọ́ eyi nisisiyi, ẹnyin aṣiwere enia ati alailọgbọ́n; ti o ni oju, ti kò si riran, ti o ni eti ti kò si gbọ́.
Ẹ kò ha bẹ̀ru mi; li Oluwa wi, ẹ kì yio warìri niwaju mi, ẹniti o fi yanrin ṣe ipãla okun, opin lailai ti kò le rekọja: ìgbì rẹ̀ kọlu u, kò si le bori rẹ̀, o pariwo, ṣugbọn kò lè re e kọja?
Ṣugbọn enia yi ni aiya isàgun ati iṣọtẹ si, nwọn sọ̀tẹ, nwọn si lọ.
Bẹ̃ni nwọn kò wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa wayi, ẹniti o fun wa ni òjo akọrọ ati arọkuro ni igba rẹ̀: ti o fi ọ̀sẹ ikore ti a pinnu pamọ fun wa.
Aiṣedede nyin ti yi gbogbo ohun wọnyi pada, ati ẹ̀ṣẹ nyin ti fà ohun rere sẹhin kuro lọdọ nyin.
Nitori lãrin enia mi ni a ri enia ìka, nwọn wò kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, nwọn dẹ okùn nwọn mu enia.
Bi àgo ti o kún fun ẹiyẹ, bẹ̃ni ile wọn kún fun ẹ̀tan, nitorina ni nwọn ṣe di nla, nwọn si di ọlọrọ̀.
Nwọn sanra, nwọn ndán, pẹlupẹlu nwọn rekọja ni ìwa-buburu, nwọn kò ṣe idajọ, nwọn kò dajọ ọ̀ran alainibaba, ki nwọn le ri rere; nwọn kò si dajọ are awọn talaka.
Emi kì yio ha ṣe ibẹwò nitori nkan wọnyi, li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lori orilẹ-ède bi eyi?
Ohun iyanu ati irira li a ṣe ni ilẹ na.
Awọn woli sọ asọtẹlẹ eke, ati awọn alufa ṣe akoso labẹ ọwọ wọn, awọn enia mi si fẹ ki o ri bẹ̃; kini ẹnyin o si ṣe ni igbẹhin rẹ̀?