Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah, woli wá si awọn orilẹ-ède.
Si Egipti, si ogun Farao-Neko, ọba Egipti, ti o wà lẹba odò Ferate ni iha Karkemiṣi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kọlu ni ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda.
Ẹ mura apata ati asà, ẹ si sunmọ tosi si oju ìja,
Ẹ di ẹṣin ni gãrì; ẹ gùn wọn, ẹnyin ẹlẹṣin, ẹ duro lẹsẹsẹ ninu akoro nyin; ẹ dan ọ̀kọ, ẹ wọ ẹwu irin.
Ẽṣe ti emi ti ri wọn ni ibẹ̀ru ati ni ipẹhinda? awọn alagbara wọn li a lù bolẹ, nwọn sa, nwọn kò si wò ẹhin: ẹ̀ru yika kiri, li Oluwa wi.
Ẹni ti o yara, kì yio salọ, alagbara ọkunrin kì yio si sala: ni iha ariwa lẹba odò Ferate ni nwọn o kọsẹ̀, nwọn o si ṣubu.
Tani eyi ti o goke wá bi odò, ti omi rẹ̀ nrú gẹgẹ bi odò wọnni?
Egipti dide bi odò Nile, omi rẹ̀ si nrú bi omi odò wọnni; o si wipe, Emi o goke lọ, emi o si bò ilẹ aiye, emi o si pa ilu ati awọn olugbe inu rẹ̀ run!
Ẹ goke wá, ẹnyin ẹṣin, ẹ si sare kikan, ẹnyin kẹ̀kẹ; ki awọn alagbara si jade wá; awọn ara Etiopia, ati awọn ara Libia, ti o ndi asà mu; ati awọn ara Lidia ti nmu ti o nfa ọrun.
Ṣugbọn ọjọ yi li ọjọ igbẹsan Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o le gbẹsan lara awọn ọta rẹ̀; idà yio si jẹ, yio si tẹ́ ẹ lọrun, a o si fi ẹ̀jẹ wọn mu u yo: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni irubọ ni ilẹ ariwa lẹba odò Euferate.
Goke lọ si Gileadi, ki o si mu ikunra, iwọ wundia, ọmọbinrin Egipti: li asan ni iwọ o lò ọ̀pọlọpọ õgùn; ọja-imularada kò si fun ọ.
Awọn orilẹ-ède ti gbọ́ itiju rẹ, igbe rẹ si ti kún ilẹ na: nitori alagbara ọkunrin ti kọsẹ lara alagbara, ati awọn mejeji si jumọ ṣubu pọ̀.
Ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun Jeremiah, woli, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli wá lati kọlu ilẹ Egipti.
Ẹ sọ ọ ni Egipti, ki ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Migdoli, ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Nofu ati Tafanesi: ẹ wipe, duro lẹsẹsẹ, ki o si mura, nitori idà njẹrun yi ọ kakiri.
Ẽṣe ti a fi gbá awọn akọni rẹ lọ? nwọn kò duro, nitori Oluwa le wọn.
A sọ awọn ti o kọsẹ di pupọ, lõtọ, ẹnikini ṣubu le ori ẹnikeji: nwọn si wipe, Dide, ẹ jẹ ki a pada lọ sọdọ awọn enia wa, ati si ilẹ ti a bi wa, kuro lọwọ idá aninilara.
Nwọn kigbe nibẹ; Farao, ọba Egipti ti ṣegbe: on ti kọja akoko ti a dá!
Bi emi ti wà, li Ọba, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, nitõtọ gẹgẹ bi Tabori lãrin awọn oke, ati gẹgẹ bi Karmeli lẹba okun, bẹ̃ni on o de.
Iwọ, ọmọbinrin ti ngbe Egipti, pèse ohun-èlo ìrin-ajo fun ara rẹ: nitori Nofu yio di ahoro, a o si fi joná, laini olugbe.
Ẹgbọrọ malu ti o dara pupọ ni Egipti, lõtọ, iparun de, o de lati ariwa!
Awọn ologun rẹ̀ ti a fi owo bẹ̀, dabi akọmalu abọpa lãrin rẹ̀; awọn wọnyi pẹlu yi ẹhin pada; nwọn jumọ sa lọ pọ: nwọn kò duro, nitoripe ọjọ wàhala wọn de sori wọn, àkoko ibẹwo wọn.
Ohùn inu rẹ̀ yio lọ gẹgẹ bi ti ejo; nitori nwọn o lọ pẹlu agbara; pẹlu àkeke lọwọ ni nwọn tọ̀ ọ wá bi awọn akégi.
Nwọn o ke igbo rẹ̀ lulẹ, li Oluwa wi, nitori ti a kò le ridi rẹ̀; nitoripe nwọn pọ̀ jù ẹlẹnga lọ, nwọn si jẹ ainiye.
Oju yio tì ọmọbinrin Egipti; a o fi i le ọwọ awọn enia ariwa.
Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe; Wò o, emi o bẹ̀ Amoni ti No, ati Farao, ati Egipti wò, pẹlu awọn ọlọla wọn, ati awọn ọba wọn; ani Farao ati gbogbo awọn ti o gbẹkẹ le e:
Emi o si fi wọn le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati le ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀: lẹhin na, a o si mã gbe inu rẹ̀, gẹgẹ bi ìgba atijọ, li Oluwa wi.
Ṣugbọn iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, má si fòya, iwọ Israeli: nitori, wo o, emi o gbà ọ là lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati ilẹ ìgbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì o si dẹ̀ru bà a.
Iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu rẹ; nitori emi o ṣe opin patapata ni gbogbo awọn orilẹ-ède, nibiti emi ti le ọ si: ṣugbọn emi kì o ṣe ọ li opin patapata, ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn; sibẹ emi kì yio jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.