Jer 32:36-41

Jer 32:36-41 YBCV

Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ilu yi, sipa eyiti ẹnyin wipe, A o fi le ọwọ ọba Babeli, nipa idà, ati nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ-arun. Wò o, emi o kó wọn jọ lati gbogbo ilẹ jade, nibiti emi ti le wọn si ninu ibinu mi, ati ninu irunu mi, ati ninu ikannu nla; emi o si jẹ ki nwọn ki o mã gbe lailewu: Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn. Emi o si fun wọn li ọkàn kan, ati ọ̀na kan, ki nwọn ki o le bẹ̀ru mi li ọjọ gbogbo, fun rere wọn, ati ti awọn ọmọ wọn lẹhin wọn: Emi o si ba wọn dá majẹmu aiyeraiye, pe emi kì o yipada lẹhin wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o fi ibẹ̀ru mi si ọkàn wọn, ti nwọn kì o lọ kuro lọdọ mi. Lõtọ, emi o yọ̀ lori wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o si gbìn wọn si ilẹ yi li otitọ tinutinu mi ati tọkàntọkàn mi.