Jer 31:1-3

Jer 31:1-3 YBCV

LI àkoko na, li Oluwa wi, li emi o jẹ Ọlọrun gbogbo idile Israeli, nwọn o si jẹ enia mi. Bayi li Oluwa wi, Enia ti o sala lọwọ idà ri ore-ọfẹ li aginju, ani Israeli nigbati emi lọ lati mu u lọ si isimi rẹ̀. Oluwa ti fi ara hàn fun mi lati okere pe, Nitõtọ emi fi ifẹni aiyeraiye fẹ ọ, nitorina ni emi ti ṣe pa ore-ọfẹ mọ fun ọ.