Jer 18:1-4

Jer 18:1-4 YBCV

Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ̀ Oluwa wipe, Dide, sọkalẹ lọ si ile amọkoko, nibẹ li emi o mu ọ gbọ́ ọ̀rọ mi. Mo si sọkalẹ lọ si ile amọkoko, sa wò o, o mọ iṣẹ kan lori kẹ̀kẹ. Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ.