Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle Oluwa, ti o si fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀! Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso. Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ? Emi, Oluwa, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀.
Kà Jer 17
Feti si Jer 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jer 17:7-10
5 Awọn ọjọ
Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò