Jer 14:7-9

Jer 14:7-9 YBCV

Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀. Iwọ, ireti Israeli, olugbala rẹ̀ ni wakati ipọnju! ẽṣe ti iwọ o dabi alejo ni ilẹ, ati bi èro ti o pa agọ lati sùn? Ẽṣe ti iwọ o dabi ẹniti o dãmu, bi ọkunrin akọni ti kò le ràn ni lọwọ? sibẹ iwọ, Oluwa, mbẹ li ãrin wa, a si npè orukọ rẹ mọ wa, má fi wa silẹ.