Jer 10:1-4

Jer 10:1-4 YBCV

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun nyin, ẹnyin ile Israeli: Bayi li Oluwa wi, Ẹ máṣe kọ́ ìwa awọn keferi, ki àmi ọrun ki o má si dãmu nyin, nitoripe, nwọn ndamu awọn orilẹ-ède. Nitori asan ni ilana awọn orilẹ-ède; nitori igi ti a ke lati igbo ni iṣẹ ọwọ oniṣọna ati ti ãke. Nwọn fi fádaka ati wura ṣe e lọṣọ, nwọn fi iṣo ati olù dì i mu, ki o má le mì.