Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède. Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun! sa wò o, emi kò mọ̀ ọ̀rọ isọ nitori ọmọde li emi. Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ. Má bẹ̀ru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gbà ọ: li Oluwa wi. Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu.
Kà Jer 1
Feti si Jer 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jer 1:5-9
6 Awọn ọjọ
Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò