A. Oni 6:3-6

A. Oni 6:3-6 YBCV

O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá; Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ. Nitoriti nwọn gòke wá ti awọn ti ohunọ̀sin wọn ati agọ́ wọn, nwọn si wá bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ́ ainiye: nwọn si wọ̀ inu ilẹ na lati jẹ ẹ run. Oju si pọ́n Israeli gidigidi nitori awọn Midiani; awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA.