A. Oni 5:24-27

A. Oni 5:24-27 YBCV

Ibukún ni fun Jaeli aya Heberi ọmọ Keni jù awọn obinrin lọ, ibukún ni fun u jù awọn obinrin lọ ninu agọ́. O bère omi, o fun u ni warà; o mu ori-amọ tọ̀ ọ wá ninu awo iyebiye. O nà ọwọ́ rẹ̀ mú iṣo, ati ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú òlu awọn ọlọnà; òlu na li o si fi lù Sisera, o gba mọ́ ọ li ori, o si gún o si kàn ẹbati rẹ̀ mọlẹ ṣinṣin. Li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu, o dubulẹ: li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu: ni ibi ti o gbè wolẹ, nibẹ̀ na li o ṣubu kú.