Ọkunrin kan ara Sora si wà, ti iṣe idile Dani, orukọ rẹ̀ si ni Manoa, obinrin rẹ̀ si yàgan, kò si bimọ. Angeli OLUWA si farahàn obinrin na, o si wi fun u pe, Sá kiyesi i, iwọ yàgan, iwọ kò si bimọ: ṣugbọn iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan. Njẹ nitorina kiyesara, emi bẹ̀ ọ, máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, má si ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini. Nigbana obinrin na wá, o si rò fun ọkọ rẹ̀, wipe, Enia Ọlọrun kan wá sọdọ mi, irí rẹ̀ si dabi irí angeli Ọlọrun, o ní ẹ̀ru gidigidi; ṣugbọn emi kò bilère ibiti o ti wá, bẹ̃li on kò si sọ orukọ rẹ̀ fun mi: Ṣugbọn on sọ fun mi pe, Kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; nitorina má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni ki o má ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá titi di ọjọ́ ikú rẹ̀.
Kà A. Oni 13
Feti si A. Oni 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: A. Oni 13:2-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò