Lati ibẹ̀ o si gbé ogun tọ̀ awọn ara Debiri lọ. (Orukọ Debiri ni ìgba atijọ si ni Kiriati-seferi.) Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o si kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. O si ṣe, nigbati Aksa dé ọdọ rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati bère oko kan lọdọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ kuro lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́? On si wi fun u pe, Ta mi lọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fi isun omi fun mi pẹlu. Kalebu si fi ìsun òke ati isun isalẹ fun u.
Kà A. Oni 1
Feti si A. Oni 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: A. Oni 1:11-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò