Jak 5:14-18

Jak 5:14-18 YBCV

Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i. Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ. Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa. O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade.