Jak 5:12-20

Jak 5:12-20 YBCV

Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi. Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ́. Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i. Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ. Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa. O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade. Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada; Jẹ ki o mọ̀ pe, ẹniti o ba yi ẹlẹṣẹ kan pada kuro ninu ìṣina rẹ̀, yio gbà ọkàn kan là kuro lọwọ ikú, yio si bò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Jak 5:12-20

Jak 5:12-20 - Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.
Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ́.
Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa:
Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i.
Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.
Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa.
O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade.
Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada;
Jẹ ki o mọ̀ pe, ẹniti o ba yi ẹlẹṣẹ kan pada kuro ninu ìṣina rẹ̀, yio gbà ọkàn kan là kuro lọwọ ikú, yio si bò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.