Jak 4:5-7

Jak 4:5-7 YBCV

Ẹnyin ṣebi iwe-mimọ́ sọ lasan pe, Ẹmí ti o fi sinu wa njowu gidigidi lori wa? Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn. Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin.