Jak 3:8-10

Jak 3:8-10 YBCV

Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni. On li awa fi nyìn Oluwa ati Baba, on li a si fi mbú enia, ti a dá li aworan Ọlọrun. Lati ẹnu kanna ni iyìn ati ẽbú ti njade. Ẹnyin ará mi, nkan wọnyi kò yẹ ki o ri bẹ̃.