Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀. Ẹnyin mọ eyi, ẹnyin ará mi olufẹ; ṣugbọn jẹ ki olukuluku enia ki o mã yara lati gbọ́, ki o lọra lati fọhùn, ki o lọra lati binu: Nitori ibinu enia kì iṣiṣẹ ododo Ọlọrun. Nitorina ẹ fi gbogbo ẽri ati buburu aṣeleke lelẹ li apakan, ki ẹ si fi ọkàn tutù gbà ọ̀rọ na ti a gbin, ti o le gbà ọkàn nyin là. Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ. Nitori bi ẹnikan ba jẹ olugbọ́ ọ̀rọ na, ti kò si jẹ oluṣe, on dabi ọkunrin ti o nṣakiyesi oju ara rẹ̀ ninu awojiji: Nitori o ṣakiyesi ara rẹ̀, o si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna o si gbagbé bi on ti ri. Ṣugbọn ẹniti o ba nwo inu ofin pipé, ofin omnira nì, ti o si duro ninu rẹ̀, ti on kò jẹ olugbọ́ ti ngbagbé, bikoṣe oluṣe iṣẹ, oluwarẹ̀ yio jẹ alabukun ninu iṣẹ rẹ̀. Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsìn Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rẹ̀ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsin oluwarẹ̀ asan ni. Ìsin mimọ́ ati ailẽri niwaju Ọlọrun ati Baba li eyi, lati mã bojutó awọn alainibaba ati awọn opó ninu ipọnju wọn, ati lati pa ara rẹ̀ mọ́ lailabawọn kuro li aiyé.
Kà Jak 1
Feti si Jak 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jak 1:18-27
4 Awọn ọjọ
Ìlànà kíkà yìí ṣe àwàjinlẹ̀ bí ebi wa láti mọ Ọlọ́run kí á sì sọ ọ́ di mímọ̀ máa ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ sínú èrèdí rẹ̀ fún ayé wa. Ṣe àwárí ohun tí ó sọ Dafidi di ẹni bí ọkàn Ọlọ́run – àti bí ìwọ pẹ̀lú ṣe lè gbé ayé pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn-kan fún Ọlọ́run, gbígbádùn ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jesu àti gbígbẹ́kẹ̀le láti tẹ́ àìní rẹ larùn.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò