Ibukún ni fun ọkunrin ti o fi ọkàn rán idanwò: nitori nigbati o ba yege, yio gbà ade ìye, ti Oluwa ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ. Ki ẹnikẹni ti a danwò máṣe wipe, Lati ọwọ́ Ọlọrun li a ti dán mi wò: nitori a kò le fi buburu dán Ọlọrun wò, on na kì isi idán ẹnikẹni wò: Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà a lọ ti a si tàn a jẹ. Njẹ, ifẹkufẹ na nigbati o ba lóyun, a bí ẹ̀ṣẹ: ati ẹ̀ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bí ikú. Ki a má ṣe tan nyin jẹ, ẹnyin ará mi olufẹ. Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida. Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀. Ẹnyin mọ eyi, ẹnyin ará mi olufẹ; ṣugbọn jẹ ki olukuluku enia ki o mã yara lati gbọ́, ki o lọra lati fọhùn, ki o lọra lati binu: Nitori ibinu enia kì iṣiṣẹ ododo Ọlọrun. Nitorina ẹ fi gbogbo ẽri ati buburu aṣeleke lelẹ li apakan, ki ẹ si fi ọkàn tutù gbà ọ̀rọ na ti a gbin, ti o le gbà ọkàn nyin là. Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ.
Kà Jak 1
Feti si Jak 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jak 1:12-22
7 Days
Have you ever been so tired or defeated in life that you’ve wanted to throw in the towel and give up? The Bible is full of encouragement to persevere and keep going! This 7-day reading plan will refresh you for the journey ahead.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò