Isa 8:21-22

Isa 8:21-22 YBCV

Nwọn o si kọja lọ lãrin rẹ̀, ninu inilara ati ebi: yio si ṣe pe nigbati ebi yio pa wọn, nwọn o ma kanra, nwọn o si fi ọba ati Ọlọrun wọn re, nwọn o si ma wò òke. Nwọn o si wò ilẹ, si kiyesi i, iyọnu ati okùnkun, iṣuju irora: a o si le wọn lọ sinu okùnkun.