Isa 46:9-11

Isa 46:9-11 YBCV

Ẹ ranti nkan iṣaju atijọ: nitori emi li Ọlọrun, ko si si ẹlomiran, emi li Ọlọrun, ko si si ẹniti o dabi emi. Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti kò ti iṣe lati igbãni wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si ṣe gbogbo ifẹ mi. Ẹniti npe idì lati ilà-õrun wá: ọkunrin na ti o mu ìmọ mi ṣẹ lati ilẹ jijìn wá: lõtọ, emi ti sọ ọ, emi o si mu u ṣẹ; emi ti pinnu rẹ̀, emi o si ṣe e pẹlu.